Baba mi

Baba mi, gba mi l’owo aye 

Baba mi gba mi o , Baba mi gba mi
Ifekufe aye, ma je ng ba won fe

Verse

B’aye ba n ye o, ore mi ko rora se.
Eniyan le pon e le, ma je ko lo s’ori e.
Moni ton ba pon e le se, mase gba a s’ori
Ko s’eni to mo o se, Oluwa l’ogo ye
Ranti pe aye alarambara o
F’eje s’inu tu’to funfun jade
Eniyan ng wo oju, Olorun ng wokan o
Aye to nipe adegun, tun le ni ade o gun mo
Aye toto aye, aye akamara o
Baba mi o Baba mi
Dakun t’ewo gba mi
Ki ng ma se jin s’ofin aye
Baba mi mo be o
Kin g ma se lu pampe aye e e e

Chorus

Baba mi gba mi lowo aye
Baba mi lorun jowo o
Gba mi lowo aye e e baba mi
Baba mi gba mi lowo aye
Eledumare 0 0 0 gba mi o
Baba mi gba mi lowo aye

Verse

Ibare aye
Isota Olorun ni
Hosanna f’omo Dafidi, t’o wa di e kan an m’ogi
Oro aye so si ni l’enu o, otun bu iyo si
Ara e so fun mi na, oro yi t’oju su mi
O nkomi l’omi’nu, ipa lo so s’iresi mi
Enit’Oluwa ko yo,
Lo yo ninu ewu
Baba mi o Baba mi,
Se amona mi
Ko mi ni ona mimo Re, to mi ni ona tito
Gba mi la Baba o dakun dabo o

Baba mi gba mi lowo aye
Iparun lere aye
Ma j eng kuna Baba
Baba mi gba mi lowo aye
Oti segun aye, f’alafia Re fun mi, Baba mi
Baba mi gba mi lowo aye

Enit’ Oluwa ba ko yo se
Ohun lo le segun aye
Di opo Oluwa mu,
D’iro mo agbelebu
Se iwon to ba le se, mase jura re lo
Iwontunwosi lo laye, ma koja aye re,
Kori kosun ore ko si mo, nothing is free laye nwi
Pa ofin Oluwa mo, fe enikeji re
Baba mi o Baba mi
Alpha Et Omega mi
Siwaju ko tun kehin fun mi
Baba mimo jowo

Baba mi gba mi lowo aye
Ohun aye a b’aye lo o o
Baba mi gba mi lowo aye

A o ma f’oju ri,
Imo eniyan buburu
Eti wa la o fi ma gbo
Ko ni sun m’etile wa
Angeli ti to ng so wa
Ma se gbabode fun wa
L’oruko Jesu
Ibi o ni y’ale wa
K’oju wa ma r’ire
T’oju owo ng ri
K’okan wa kun f’ayo
Bi ago olododo
Mase pa oju Re mo,
Kuro lodo wa
Mase binu sa wa ti laye
Jowo mase ko wa
K’aye ma bere p’Olorun wa da
Baba s’anu fun wa
Ore mi teti ko gbo ye ye ye,
Fi iye si oro mi
Kosi b’orun ti le mu to laye.
Sanmo dudu a wa
Bo ti wu k’ekun pe d’ale to
Ayo mbo lowuro o
Nitorina duro de Oluwa,
Tu oju re ka
Yio si mu o laye le o, Ore
Duro de Oluwa

Baba mi gba mi lowo aye

Ye o, ye o, ye o, ye o
Baba mi gba mi o
Mo sa to O wa
Se imole ati igbala mi
Kin g ma se dapo m’aye
Ro mi l’agbara
We mi s’inu ibu eje Jesu
K’ogun aye ma bo’ori mi k’adun aye ma fa mi
Pa luciferi l’enu mo o Baba
Wa ba mi gbe
Wa ba migbe
Mo ke pe O o Baba
O gbekun omo ta ti were
Gb ani gba ni , n’igba ‘danwo
Oba a s’oro ma ye
Oba a soro ma tase
Olowo gbogboro ti ng y’omo ninu ofin
S’odi ati asa mi
Mo di opo Re mu
Gbongbo idile Jese
Baba alai ni baba
Kiniun eya Judah
Oba to luti kara bi ajere
Oba ti nje Emi ni
Emi ni mase beru
Iyingbinikin arugbo ojo
Ewu ori ko so d’arugbo
Irun funfun O so d’ole
Oba lana, loni
Oba titi aye
Bi agbonrin tin g mi hele
Si ipado omi
Oluwa, be lokan mi nmi si O
Oluwa awon omo ogun
Baba mi l’orun mo de
Jesu Kristi gba mi o
Emimimo gba mi o
Ta lo le mo isina re
We mi kuro ninu isise ikoko
K’ese ma joba lori mi
K’emi le duro sinsin
Je ki oro enu mi o
Ati isaro okan mi
Je itewo gba l’oju Re o Baba
Oludande mi
Oro yi ngbe mi lokan gidi gan o

Gba mi l’owo Aye

 
 

 

en_USEnglish