tribute

Ta l’oloko to wa mi wa s’aye

Ta l’oloko to wa mi wa si’le aye

F’osu mesan gbako inu ta ni mo gbe

Abiyamo ti ki i f’omo sere

Asoja mora bi ihamora ologun

Iya ni wura eh eh eh aah

Abiyamo ododo

O gbekun omo ta ti were

Alabaro ni, Olugbowo ni

Ki ni mo le fi s’akawe mama to bi mi

Bawo ni mo se le san ore ti iya se fun mi

Ore to se ko se d’iye le

Mo kan sara si e o mama mi

Iya abiye o seun

Ah ah ah ah. Eh eh eh eh eh eh


Iya ni wura, baba ni jigi

Bi ko ba si t’isu, ki la fe ma pe n’iyan

Bi ko ba si t’agbado to tape ni yeri ile

To se ‘rugbon yeri yeri, ki la fe ma pe leko yangan

Amala dun lati je, sugbon ko sehin elubo

Bi ko ba si t’obi mi, bus stop ni mba duro si

Oluwa to f’ omo si ike obi, O mo ohun to nse

Modupe lowo obi mi, ti won ko wo se (wash) mi danu

Won bi mi si’le aye tan, won tun se toju to to

Nigba o jo, nigba erun won ofi nkan kan won mi

Orisun omo l’obi je, Orisun ma le gbagbe


Ta l’oloko to wa mi wa s’aye

F’osu mesan gbako inu ta ni mo gbe

Abiyamo ti ki i f’omo sere

Asoja mora bi ihamora ologun

Osu mesan lo fi ru mi kiri

Iya a b’oja gboro gboro

Odun meta lo fi gbe mi pon

Emi ko le sai ma ranti

Gbogbo wahala iya mi

To ntoju mi t’osan t’oru

Ninu ebi ninu ayo

Ninu ekun ninu erin

Moni ninu ebi ninu ayo se

Ninu oungbe ninu ayo

Mama mama

B’ebi ng p’omoi, a wa ounje lo

B’omo o jeun, ko ni jeun

Ah agborodun bi ire s’owon

Agborandun bi iya ko si

Alagbo omo ni iya je

Omo ti ko n’iya ki degbo eyin ni won nwi

Toto se bi owe eyin agba iba mo toro

Laala obi lori omo ko lafi we

A mu mora iya lori omo po, ko se f’enu so


Lojo ori fifo, (ehn)

lojo inu rirun (ehn)

Lojo ai r’orun sun o (ehn)

Nigba t’ebi ba wo ‘nu (ehn)

Nigba igbonara (ehn)

Igba teyin ba ng yo (ehn)

Ambeletase (ehn)

Ojo bibi omo (ehn)


Ori ire lo je f’omo, to gba ‘re l’enu baba re

Idunnu nla ni f’omo ti baba re sure fun

Ako le ki mama, ka mi fi ti baba se

Igi kan ki i da ‘gbo se, Sese kan kii dede se o

Eeyan lo ng mbe n’idi oro, t’oro fi n ke

Ina o le g’oke odo lai ko ba l’awo lehin

Baba lawo ko se omo, se b’ohun la toka

Baba l’olugbejo,

Oludamonran f’ologbon omo


Oluwa orun on aye, oruko Re ti n’iyin to Baba

Ti tobi ninu ola nla Kabi e osi rara

Oun to ba fi fun ni, sebi tori iyonu Reni

Eyi to ba gba kuro, Oluwa iwo lo ye.

Olorun mo gba fun O, nko je f’apa jana


Bridge

Ta l’oloko to wa mi wa s’aye Mama

F’osu mesan gbako inu ta ni mo gbe Mama mi ni

Abiyamo ti ki i f’omo sere Mama

Asoja mora bi ihamora ologun Mama mi ni

Ara Iya ni wura iyebiye, Iya lolugbowo mi, Abiyamo otito


Omo olumushin anakoru,

Ti ki i je ounje imele

Akinkanju obinrin

To se e fi yangan l’awujo

Mama oni wa r ere

Iye re k’oja iyun

O fowo sise tinutinu

O tun nawo si gbogbo eniyan

Ogobon lo fi i yanu,

Li ahon re lofin iseun

Alabunkunfun lo je

Ara ile re fiyin fun o

Opolopo lon huwa rere

Ise re ta gbogbo won yo

Iyin to si e mama,

‘Tori to beru Oluwa

Ise rere re o

Yoo ma yin o lenu bode

en_USEnglish